Àti pé (A tẹ) atẹ́gùn lórí bá fún (Ànábì) Sulaemọ̄n, ìrìn oṣù kan ni ìrìn òwúrọ̀ rẹ̀, ìrìn oṣù kan sì ni ìrìn ìrọ̀lẹ́ rẹ̀[1]. A sì mú kí odò idẹ máa ṣàn nínú ilẹ̀ fún un. Ó sì wà nínú àwọn àlùjànnú, èyí tó ń ṣiṣẹ́ (fún un) níwájú rẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Olúwa rẹ̀. Àti pé ẹni tí ó bá yẹ̀ kúrò níbi àṣẹ Wa nínú wọn, A máa fún un ní ìyà iná tó ń jó tọ́ wò. 1