Àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí lọ́kùnrin àti àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmọ́ lóbìnrin, irú kan-ùn ni wọ́n; wọ́n ń pàṣẹ ohun burúkú, wọ́n ń kọ ohun rere, wọ́n sì ń káwọ́ gbera (láti náwó fẹ́sìn). Wọ́n gbàgbé Allāhu. Nítorí náà, Allāhu gbàgbé wọn.[1] Dájúdájú àwọn ṣọ̀bẹ-ṣèlu mùsùlùmí, àwọn ni òbìlẹ̀jẹ́. 1