Allāhu ṣe ibùsinmi fún yín sínú ilé yín. Láti ara awọ ẹran-ọ̀sìn, Ó tún ṣe àwọn ilé (àtíbàbà) kan tó fúyẹ́ fún yín láti gbé rìn ní ọjọ́ ìrìn-àjò yín àti ní ọjọ́ tí ẹ bá wà nínú ìlú. Láti ara irun àgùtàn,[1] irun ràkúnmí àti irun ewúrẹ́, ẹ tún ń rí àwọn n̄ǹkan ọ̀ṣọ́ àti n̄ǹkan ìgbádùn lò títí fún ìgbà díẹ̀. 1