Lẹ́yìn náà, A sọ àtọ̀ di ẹ̀jẹ̀ dídì. Lẹ́yìn náà, A sọ ẹ̀jẹ̀ dídì di bááṣí ẹran. Lẹ́yìn náà, A sọ bááṣí ẹran di eegun. Lẹ́yìn náà, A fi ẹran bo eegun. Lẹ́yìn náà, A sọ ọ́ di ẹ̀dá mìíràn.[1] Nítorí náà, ìbùkún ni fún Allāhu, Ẹni tó dára jùlọ nínú àwọn ẹlẹ́dàá (oníṣẹ́-ọnà). 1