Ti Allāhu ni ibùyọ òòrùn àti ibùwọ̀ òòrùn. Nítorí náà, ibikíbi tí wọ́n bá dojú yín kọ ibẹ̀ yẹn náà ni ojú rere Allāhu (ìyẹn ni pé, ẹ ti dojúkọ Allāhu ní ibi tí wọ́n bá pa yín láṣẹ pé kí ẹ dojúkọ kírun.) Dájúdájú Allāhu ni Olùgbààyè, Onímọ̀.[1] 1