Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un (fún ìbánisọ̀rọ̀ náà), Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀.[1] (Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó jí, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi.)² 1