Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo lọ́kùnrin, nígbà tí ẹ bá fẹ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo lóbìnrin,[1] lẹ́yìn náà tí ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣíwájú kí ẹ tó bá wọn ní àṣepọ̀ lọ́kọ-láya, kò sí opó ṣíṣe kan tí wọn yóò ṣe fún yín. Nítorí náà, ẹ fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ̀sílẹ̀. Kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ ní ìfisílẹ̀ tó rẹwà. 1