Nítorí náà, nígbà tí ẹ bá pàdé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ (lójú ogun ẹ̀sìn), ẹ máa bẹ́ wọn lọ́rùn ǹsó títí di ìgbà tí ẹ máa fi rí wọn pa dáadáa. (Nígbà tí ọwọ́ yín bá ti bà wọ́n tán), ẹ dè wọ́n mọ́lẹ̀ sórí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, ẹ lè tú wọn sílẹ̀ ní ọ̀fẹ́ tàbí kí ẹ tú wọn sílẹ̀ pẹ̀lú owó ìtúsílẹ̀ títí kò fi níí sí ogun ẹ̀sìn mọ́.1 Ìyẹn (wà bẹ́ẹ̀). Tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, ìbá gbẹ̀san fúnra Rẹ̀ (láì níí la ogun lọ), ṣùgbọ́n nítorí kí Ó lè dán apá kan yín wò lára apá kan ni. Àwọn mùsùlùmí tí wọ́n sì pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu, Allāhu kò níí sọ iṣẹ́ wọn dòfo. 1