Èyí ni ẹ̀dá ti Allāhu. Nítorí náà, ẹ fi ohun tí àwọn mìíràn lẹ́yìn Rẹ̀ dá hàn mí! Rárá o! Àwọn alábòsí wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé ni.
(Rántí) nígbà tí Luƙmọ̄n sọ fún ọmọ rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe wáàsí fún un, pé: “Ọmọ mi, má ṣe ṣẹbọ sí Allāhu. Dájúdájú ẹbọ ṣíṣe ni àbòsí ńlá.
Nígbà tí wọ́n bá sì sọ fún wọn pé: “Ẹ tẹ̀lé ohun tí Allāhu sọ̀kalẹ̀.” Wọ́n á wí pé: “Rárá! A máa tẹ̀lé ohun tí a bá lọ́wọ́ àwọn bàbá wa ni.” (Ṣé wọn yóò tẹ̀lé àwọn bàbá wọn) t’òhun ti bí aṣ-Saetọ̄n ṣe ń pè wọ́n síbi ìyà Iná tó ń jò fòfò?
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣàì gbàgbọ́, má ṣe jẹ́ kí àìgbàgbọ́ rẹ̀ kó ìbànújẹ́ bá ọ. Ọ̀dọ̀ Wa ni ibùpadàsí wọn. Nígbà náà, A máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá.
Dájúdájú tí o bá bi wọ́n léèrè pé: “Ta ni Ó dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀?”, dájúdájú wọ́n á wí pé: “Allāhu ni.” Sọ pé: “Gbogbo ẹyìn ń jẹ́ ti Allāhu, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ wọn kò mọ̀.
يا ايها الناس اتقوا ربكم واخشوا يوما لا يجزي والد عن ولده ولا مولود هو جاز عن والده شييا ان وعد الله حق فلا تغرنكم الحياة الدنيا ولا يغرنكم بالله الغرور ٣٣
Dájúdájú Allāhu, ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìmọ̀ Àkókò náà wà. Ó ń sọ òjò kalẹ̀. Ó mọ ohun tó wà nínú àpòlùkẹ́.1 Ẹ̀mí kan kò sì mọ ohun tí ó máa ṣe níṣẹ́ ní ọ̀la. Ẹ̀mí kan kò sì mọ ilẹ̀ wo l’ó máa kú sí. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀, Alámọ̀tán.