Àwọn tó gbé Ìtẹ́-ọlá náà rù àti àwọn tó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n ń ṣe àfọ̀mọ́ pẹ̀lú ìdúpẹ́ fún Olúwa wọn. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu. Wọ́n sì ń tọrọ àforíjìn fún àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo (báyìí pé): “Olúwa wa, ìkẹ́ àti ìmọ̀ (Rẹ) gbòòrò ju gbogbo n̄ǹkan lọ, nítorí náà, ṣàforíjìn fún àwọn tó ronú pìwàdà, tí wọ́n sì tẹ̀lé ojú-ọ̀nà Rẹ. Kí O sì ṣọ́ wọn nínú ìyà iná Jẹhīm.