Ìwọ Ànábì, nígbà tí ẹ bá fẹ́ kọ àwọn obìnrin sílẹ̀, ẹ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ tí wọ́n máa ṣe.[1] Kí ẹ sì ṣọ́ òǹkà ọjọ́ opó ìkọ̀sílẹ̀ náà. Kí ẹ bẹ̀rù Allāhu, Olúwa yín. Ẹ má ṣe mú wọn jáde kúrò nínú ilé wọn, àwọn náà kò sì gbọdọ̀ jáde àfi tí wọ́n bá lọ ṣe ìbàjẹ́ tó fojú hàn. Ìwọ̀nyẹn sì ni àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà òfin tí Allāhu gbékalẹ̀, o kúkú ti ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara rẹ̀. Ìwọ kò sì mọ̀ bóyá Allāhu máa mú ọ̀rọ̀ titun kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. 1