Rántí nígbà tí Ànábì bá ọ̀kan nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ s’ọ̀rọ̀ àṣírí. Nígbà tí (ẹni tó bá sọ̀rọ̀, ìyẹn Hafsọh) sì sọ̀rọ̀ náà fún (‘Ā’iṣah), Allāhu sì fi han Ànábì (pé ẹlòmíìràn ti gbọ́ sí i).[1] Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - sì sọ apá kan rẹ̀ (fún Hafsọh pé: “O ti fi ọ̀rọ̀ Mọ̄riyah tó ‘Ā’iṣah létí.”). Ó sì fi apá kan sílẹ̀ (ìyẹn, ọ̀rọ̀ nípa ipò àrólé). Àmọ́ nígbà tí (Ànábì) fi ìró náà tó o létí, Hafsọh) sọ pé: “Ta ni ó fún ọ ní ìró èyí?” (Ànábì) sọ pé: “Onímọ̀, Alámọ̀tán l’Ó fún mi ní ìró náà.” 1