O máa rí àwọn alábòsí tí wọn yóò máa páyà nítorí ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, tí ó sì máa kò lé wọn lórí. Àwọn tó sì gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n ṣe iṣẹ́ rere máa wà ní àwọn àbàtà Ọgbà Ìdẹ̀ra,[1]. Ohun tí wọ́n bá ń fẹ́ máa wà fún wọn ní ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. Ìyẹn, òhun ni oore àjùlọ tó tóbi. 1