Nítorí náà, dojú rẹ kọ ẹ̀sìn náà, (kí o jẹ́) olùdúró-déédé-nínú-ẹ̀sìn Islām, ẹ̀sìn àdámọ́ Allāhu èyí tí Ó dá mọ́ àwọn ènìyàn. Kò sí ìyípadà fún ẹ̀sìn Allāhu.[1] (ìyẹn ni pé, ẹ kò gbọ́dọ̀ yí ẹ̀sìn Allāhu padà.)² Ìyẹn ni ẹ̀sìn tó fẹsẹ̀rinlẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn kò mọ̀.³ 1