Kí àwọn tí kò ní (ìkápá) ìgbéyàwó mú ojú wọn kúrò níbi ìṣekúṣe títí Allāhu yóò fi rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ nínú ọlá Rẹ̀.[1] Àwọn tó ń wá ìwé òmìnira nínú àwọn ẹrú yín, ẹ kọ ìwé òmìnira fún wọn tí ẹ bá mọ ohun rere nípa wọn. Kí ẹ sì fún wọn nínú dúkìá Allāhu tí Ó fún yín. (Nítorí dúkìá ayé tí ẹ̀ ń wá), ẹ má ṣe jẹ àwọn ẹrúbìnrin yín nípá láti lọ ṣe sìná, tí wọ́n bá fẹ́ ṣọ́ abẹ́ wọn níbi ìṣekúṣe.² Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ wọ́n nípá, dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run lẹ́yìn tí ẹ ti jẹ wọ́n nípá.³ 1