Ṣé ìwọ kò wòye sí àwọn tí A sọ fún pé: “Ẹ káwọ́ ró (ẹ má ì jagun ẹ̀sìn, àmọ́) ẹ máa kírun, kí ẹ sì máa yọ Zakāh.” Ṣùgbọ́n nígbà tí A ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wọn lórí, ìgbà náà ni apá kan nínú wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn bí ẹni tí ń bẹ̀rù Allāhu tàbí tí ìbẹ̀rù rẹ̀ le koko jùlọ. Wọ́n sì wí pé: “Olúwa wa, nítorí kí ni O fi ṣe ogun ẹ̀sìn ní ọ̀ran-anyàn lé wa lórí? Kúkú lọ́ wa lára di ìgbà díẹ̀ sí i.[1]” Sọ pé: “Bín-íntín ní ìgbádùn ayé, ọ̀run lóore jùlọ fún ẹni tó bá bẹ̀rù Allāhu. Wọn kò sì níí fi (ohun tó tó) ìbójú kóró èso dàbínù ṣàbòsí sí yín.”² 1