A kò rán Òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ àfi nítorí kí wọ́n lè tẹ̀lé e pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Tí ó bá jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n wá bá ọ,[1] wọ́n sì tọrọ àforíjìn Allāhu, tí Òjíṣẹ́ sì tún bá wọn tọrọ àforíjìn, wọn ìbá kúkú rí Allāhu ní Olùgba-ìronúpìwàdà, Àṣàkẹ́-ọ̀run. 1