Àwọn ọkùnrin ni òpómúléró[1] fún àwọn obìnrin nítorí pé, Allāhu ṣ’oore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan² àti nítorí ohun tí wọ́n ń ná nínú dúkìá wọn.³ Àwọn obìnrin rere ni àwọn olùtẹ̀lé-àṣẹ (Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, lẹ́yìn náà àṣẹ ọkọ), àwọn olùṣọ́-ẹ̀tọ́ ọkọ ní kọ̀rọ̀ fún wí pé Allāhu ṣọ́ (ẹ̀tọ́ tiwọn náà fún wọn lọ́dọ̀ ọkọ wọn). Àwọn tí ẹ sì ń páyà oríkunkun wọn⁴, ẹ ṣe wáàsí fún wọn, ẹ takété sí ibùsùn wọn, ẹ lù wọ́n (láì níí kó ìnira bá wọn). Tí wọ́n bá sì tẹ̀lé àṣẹ yín, ẹ má ṣe fí ọ̀nà kan kan wá wọn níjà⁵. Dájúdájú Allāhu ga, Ó tóbi.⁶ 1