Nítorí náà, àwọn mọlāika pè é nígbà tí ó ń kírun lọ́wọ́ nínú ilé ìjọ́sìn, (wọ́n sọ pé): “Dájúdájú Allāhu ń fún ọ ní ìró ìdùnnú nípa (bíbí) Yahyā. Ó máa fi òdodo rinlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ Allāhu.[1] (Ó máa jẹ́) aṣíwájú, tí kò kúndùn obìnrin.² (Ó máa jẹ́) Ànábì. Ó sì wà nínú àwọn ẹni rere.” 1