Kò lẹ́tọ̀ọ́ fún Ànábì kan láti jí mú nínú ọrọ̀ ogun ṣíwájú kí wọ́n tó pín in. Ẹnikẹ́ní tí ó bá mú nínú ọrọ̀ ogun lọ́nà ìjàǹbá ṣíwájú kí wọ́n tó pín in, ó máa dá ohun tí ó jí mú nínú ọrọ̀ ogun náà padà ní Ọjọ́ Àjíǹde. Lẹ́yìn náà, A óò san ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀san ohun tí ó ṣe níṣẹ́ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. A ò sì níí ṣe àbòsí sí wọn.