Lẹ́yìn náà, Ó sọ ìfàyàbalẹ̀ kalẹ̀ fún yín lẹ́yìn ìbànújẹ́; òògbé ta igun kan lọ nínú yín. Igun kan tí ẹ̀mí ara wọn sì ti kó èrò bá, tí wọ́n sì ń ní èròkérò sí Allāhu lọ́nà àìtọ́, èròkérò ìgbà àìmọ̀kan, wọ́n sì ń wí pé: “Ǹjẹ́ a ní àṣẹ kan (tí a lè mú wá) lórí ọ̀rọ̀ náà bí!” Sọ pé: “Dájúdájú gbogbo àṣẹ ń jẹ́ ti Allāhu pátápátá.” Wọ́n ń fi pamọ́ sínú ọkàn wọn ohun tí wọn kò lè ṣàfi hàn rẹ̀ fún ọ. Wọ́n ń wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé a ní àṣẹ kan lórí ọ̀rọ̀ náà ni, wọn ìbá tí pa wá síbí.” Sọ pé: “Tí ó bá jẹ́ pé ẹ wà nínú ilé yín, àwọn tí A ti kọ àkọọ́lè pípa sí ibùjàgun wọn mọ ìbá kúkú jáde lọ síbẹ̀.”[1] (Ogun yìí rí bẹ́ẹ̀) nítorí kí Allāhu lè gbìdánwò ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà yín àti nítorí kí Ó lè ṣàfọ̀mọ́ ohun tí ń bẹ nínú ọkàn yín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa ohun tí ń bẹ nínú igbá-àyà ẹ̀dá. 1