Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe mú ọ̀tá Mi àti ọ̀tá yín ní ọ̀rẹ́ tí ẹ óò máa fi ìfẹ́ hàn sí. Wọ́n kúkú ti ṣàì gbàgbọ́ nínú ohun tí ó dé ba yín nínú òdodo. Wọ́n yọ Òjíṣẹ́ àti ẹ̀yin náà kúrò nínú ìlú nítorí pé, ẹ gbàgbọ́ nínú Allāhu, Olúwa yín. Tí ẹ̀yin bá jáde fún ogun ní ojú-ọ̀nà Mi àti nítorí wíwá ìyọ́nú Mi, (ṣé) ẹ̀yin yóò tún máa ní ìfẹ́ kọ̀rọ̀ sí wọn ni! Èmi sì nímọ̀ jùlọ nípa ohun tí ẹ fi pamọ́ àti ohun tí ẹ fi hàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ nínú yín, dájúdájú ó ti ṣìnà kúrò lójú ọ̀nà tààrà.