Sọ pé: “Ẹ̀yin onítírà, ẹ má ṣe tayọ ẹnu-ààlà nínú ẹ̀sìn yín, (ẹ má sọ ohun tí) kì í ṣe òdodo. Ẹ má sì ṣe tẹ̀lé ìfẹ́-inú ìjọ kan tó ti ṣìnà ṣíwájú (ìyẹn, àwọn yẹhudi). Wọ́n ṣi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ lọ́nà. Wọ́n sì ṣìnà kúrò ní ojú ọ̀nà tààrà.”