Wọ́n kúkú ti di kèfèrí, àwọn tó wí pé: “Dájúdájú Allāhu ni Ìkẹta (àwọn) mẹ́ta.” Kò sì sí ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Ọlọ́hun, Ọ̀kan ṣoṣo. Tí wọn kò bá jáwọ́ níbi ohun tí wọ́n ń wí, dájúdájú ìyà ẹlẹ́ta eléro l’ó máa jẹ àwọn tó di kèfèrí nínú wọn.