Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹnikẹ́ni tí ó bá pẹ̀yìndà níbi ẹ̀sìn rẹ̀ nínú yín, láìpẹ́ Allāhu máa mú àwọn ènìyàn kan wá; Ó máa nífẹ̀ẹ́ wọn, àwọn náà máa nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Wọn yóò rọ̀ fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Wọn yó sì le mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Wọn yóò máa jagun sí ojú-ọ̀nà Allāhu. Wọn kò sì níí bẹ̀rù èébú eléèébú. Ìyẹn ni oore àjùlọ Allāhu. Ó ń fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Allāhu sì ni Olùgbòòrò, Onímọ̀