Ìwọ Òjíṣẹ́, má ṣe jẹ́ kí ó bà ọ́ nínú jẹ́ àwọn tó ń yára lọ sínú àìgbàgbọ́ nínú àwọn tó fi ẹnu ara wọn wí pé: “A gbàgbọ́.” - tí ọkàn wọn kò sì gbàgbọ́ ní òdodo - àti àwọn tó di yẹhudi, tí wọ́n ń tẹ́tí sí irọ́, tí wọ́n sì ń tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn mìíràn tí kò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, tí wọ́n ń yí ọ̀rọ̀ padà kúrò ní àwọn àyè rẹ̀, wọ́n sì ń wí pé: “Tí wọ́n bá fún yín ní èyí ẹ gbà á. Tí wọn kò bá sì fún yín ẹ ṣọ́ra.”[1] Ẹnikẹ́ni tí Allāhu bá fẹ́ fòòró rẹ̀, o ò ní ìkápá kiní kan lọ́dọ̀ Allāhu fún un. Àwọn wọ̀nyẹn ni àwọn tí Allāhu kò fẹ́ fọ ọkàn wọn mọ́. Ìdójútì ń bẹ fún wọn ní ayé. Ìyà ńlá sì ń bẹ fún wọn ní ọ̀run. 1