(Tírà tó yanjú náà, al-Ƙur’ān), Allāhu ń fi ṣe ìmọ̀nà fún ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé (àwọn n̄ǹkan) tí Allāhu yọ́nú sí, àwọn ọ̀nà àlàáfíà (àwọn ọ̀nà ọlà). Ó sì ń mú wọn jáde láti inú àwọn òkùnkùn wá sínú ìmọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Ó sì ń tọ́ wọn sí ọ̀nà tààrà (’Islām).