(Rántí) nígbà tí Allāhu sọ pé: “‘Īsā ọmọ Mọryam, rántí ìdẹ̀ra Mi lórí rẹ àti lórí ìyá rẹ, nígbà tí Mo fi ẹ̀mí Mímọ́ (mọlāika Jibrīl) ràn ọ́ lọ́wọ́, tí o sì ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ lórí ìtẹ́ ní òpóǹló àti nígbà tí o dàgbà. (Rántí) nígbà tí Mo fún ọ ní ìmọ̀ Tírà, òye ìjìnlẹ̀, at-Taorāh àti al-’Injīl. (Rántí) nígbà tí ò ń mọ n̄ǹkan láti inú amọ̀ bí ìrísí ẹyẹ, tí ò ń fẹ́ atẹ́gùn sínú rẹ̀, tí ó ń di ẹyẹ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. Ò ń wo afọ́jú àti adẹ́tẹ̀ sàn pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí ò ń mú àwọn òkú jáde (ní alààyè láti inú sàréè) pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Mi. (Rántí) nígbà tí Mo dí àwọn ọmọ ’Isrọ̄’īl lọ́wọ́ fún ọ,[1] nígbà tí o mú àwọn ẹ̀rí tó yanjú wá bá wọn. Àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn sì wí pé: “Kí ni èyí bí kò ṣe idán pọ́nńbélé.” 1