Àwọn tó ń gbé nínú ìlú Mọdīnah, tí wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ òdodo ṣíwájú wọn,[1] wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn tó fi ìlú Mọkkah sílẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ wọn (ní ìlú Mọdīnah). Wọn kò sì ní bùkátà kan nínú igbá-àyà wọn sí n̄ǹkan tí wọ́n bá fún wọn. Wọ́n sì ń gbé àjùlọ fún wọn lórí ẹ̀mí ara wọn, kódà kí ó jẹ́ pé àwọn gan-an ní bùkátà (sí ohun tí wọ́n fún wọn). Ẹnikẹ́ni tí A bá ṣọ́ níbi ahun àti ọ̀kánjúà inú ẹ̀mí rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni olùjèrè. 1