(Àwọn ni) àwọn tí wọ́n lé jáde kúrò nínú ìlú wọn ní ọ̀nà àìtọ́ àfi (nítorí pé) wọ́n ń sọ pé: “Allāhu ni Olúwa wa.” Tí kò bá jẹ́ pé Allāhu ń dènà (aburú) fún àwọn ènìyàn ni, tí Ó ń fi apá kan wọn dènà (aburú) fún apá kan, wọn ìbá ti wó ilé ìsìn àwọn fadá, ṣọ́ọ̀ṣì, sínágọ́gù àti àwọn mọ́sálásí tí wọ́n ti ń dárúkọ Allāhu ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀.[1] Dájúdájú Allāhu yóò ṣe àrànṣe fún ẹnikẹ́ni tó ń ran (ẹ̀sìn ’Islām) Rẹ̀ lọ́wọ́. Dájúdájú Allāhu mà ni Alágbára, Olùborí. 1