Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni. (Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”² Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀. 1