Sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ọ̀tá fún (mọlāika) Jibrīl,[1] (ó ti di ọ̀tá Allāhu) nítorí pé, dájúdájú (mọlāika) Jibrīl ló sọ al-Ƙur’ān kalẹ̀ sínú ọkàn rẹ pẹ̀lú àṣẹ Allāhu. Al-Ƙur’ān sì ń fi ohun tó jẹ́ òdodo rinlẹ̀ nípa èyí tó wá ṣíwájú rẹ̀. Ó jẹ́ ìmọ̀nà àti ìdùnnú fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo. 1