Ti Allāhu ni ohunkóhun tó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun tó wà nínú ilẹ̀. Tí ẹ bá ṣàfi hàn ohun tó wà nínú ẹ̀mí yín, tàbí ẹ fi pamọ́, Allāhu yó ṣírò rẹ̀ fún yín[1]. Lẹ́yìn náà, Ó máa foríjin ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì máa jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. 1