Nígbà tí (Ànábì) ’Ibrọ̄hīm sọ pé: “Olúwa mi, fi hàn mí bí Ìwọ yó ṣe sọ àwọn òkú di alààyè.” (Allāhu) sọ pé: “Ṣé ìwọ kò gbàgbọ́ ni?” Ó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni (mo gbàgbọ́), ṣùgbọ́n kí ọkàn mi lè balẹ̀ ni”. (Allāhu) sọ pé: “Mú mẹ́rin nínú àwọn ẹyẹ, kí o so wọ́n mọ́lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ (kí o pa wọ́n, kí o sì gún wọn papọ̀ mọ́ra wọn). Lẹ́yìn náà, fi ìpín nínú wọn sórí àpáta kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, pè wọ́n. Wọ́n máa sáré wá bá ọ. Kí o sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Ọlọ́gbọ́n.”