Àwọn Òjíṣẹ́ wọ̀nyẹn, A ṣoore àjùlọ fún apá kan wọn lórí apá kan. Ó ń bẹ nínú wọn, ẹni tí Allāhu bá sọ̀rọ̀ (tààrà). Ó sì ṣe àgbéga àwọn ipò fún apá kan wọn. A fún (Ànábì) ‘Īsā ọmọ Mọryam ní àwọn ẹ̀rí tó yanjú. A tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ (ìyẹn, mọlāika Jibrīl) ràn án lọ́wọ́. Àti pé tí ó bá jẹ́ pé Allāhu bá fẹ́, àwọn tó wá lẹ́yìn wọn ìbá tí bára wọn jà lẹ́yìn tí àwọn ẹ̀rí tó yanjú ti dé bá wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n yapa-ẹnu (lórí ẹ̀sìn ’Islām). Ó ń bẹ nínú wọn ẹni tó gbàgbọ́ ní òdodo (tí ó jẹ́ mùsùlùmí). Ó sì ń bẹ nínú wọn ẹni tó ṣàì gbàgbọ́ (tí ó di nasọ̄rọ̄).[1] Àti pé tí Allāhu bá fẹ́, wọn ìbá tí bá’ra wọn jà, ṣùgbọ́n Allāhu ń ṣe ohun tí Ó bá fẹ́. 1