Nígbà tí ẹ bá kọ àwọn obìnrin sílẹ̀ (ní ẹ̀ẹ̀ kíní tàbí ẹ̀ẹ̀ kejì), tí wọ́n sì parí àsìkò (opó) wọn, ẹ má ṣe dí wọn lọ́wọ́ láti fẹ́ ọkọ wọn (padà), nígbà tí wọ́n bá jọ yọ́nú síra wọn (tí wọ́n sì gba) ọ̀nà tó dára. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fún ẹnikẹ́ni nínú yín, tó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn l’ó fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Ó sì tún ṣàfọ̀mọ́ (ọkàn yín) jùlọ. Allāhu nímọ̀, ẹ̀yin kò sì nímọ̀.[1] 1