Ẹ̀ẹ̀ mejì ni ìkọ̀sílẹ̀. Nítorí náà, ẹ mú wọn mọ́ra pẹ̀lú dáadáa tàbí kí ẹ fi wọ́n sílẹ̀ pẹ̀lú dáadáa. Kò sì lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti gba kiní kan nínú ohun tí ẹ ti fún wọn àyàfi tí àwọn méjèèjì bá ń páyà pé àwọn kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu (láààrin ara wọn). Nítorí náà, tí ẹ bá páyà pé àwọn méjèèjì kò níí lè ṣọ́ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) Allāhu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún wọn nígbà náà nípa ohun tí obìnrin bá fi ṣèràpadà (ẹ̀mí ara rẹ̀).[1] Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe tayọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tayọ àwọn ẹnu-ààlà (òfin) tí Allāhu gbékalẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn gan-an ni alábòsí. 1