Wọ́n ṣe alẹ́ ààwẹ̀ ní ẹ̀tọ́ fún yín láti súnmọ́ àwọn ìyàwó yín; àwọn ni aṣọ yín, ẹ̀yin sì ni aṣọ wọn. Allāhu mọ̀ pé dájúdájú ẹ̀ ń tan ara yín jẹ (nípa àìfẹ́ sun oorun ìfẹ́ ní alẹ́ ààwẹ̀). Ó ti gba ìronúpìwàdà yín, Ó sì ṣe àmójúkúrò fún yín. Ní báyìí, ẹ súnmọ́ wọn, kí ẹ sì wá ohun tí Allāhu kọ mọ́ yín (ní ọmọ). Ẹ jẹ, ẹ mu títí ẹ óò fi rí ìyàtọ̀ láààrin òwú funfun (ìyẹn, ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀) àti òwú dúdú (ìyẹn, òkùnkùn òru) nípasẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́ òdodo. Lẹ́yìn náà, ẹ parí ààwẹ̀ náà sí alẹ́ (nígbà tí òòrùn bá wọ̀). Ẹ má ṣe súnmọ́ wọn nígbà tí ẹ bá ń kóra ró nínú àwọn mọ́sálásí. Ìwọ̀nyẹn ni àwọn ẹnu-ààlà (òfin tí) Allāhu (gbékalẹ̀), ẹ má ṣe súnmọ́ ọn (ẹ má ṣe kọlu àwọn òfin náà). Báyẹn ni Allāhu ṣe ń ṣàlàyé àwọn āyah Rẹ̀ fún àwọn ènìyàn nítorí kí wọ́n lè bẹ̀rù (Rẹ̀).