Tàbí ẹ̀ ń wí pé: “Dájúdájú (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb, wọ́n jẹ́ yẹhudi tàbí nasọ̄rọ̄.”[1] Sọ pé: “Ṣé ẹ̀yin lẹ nímọ̀ jùlọ (nípa wọn ni) tàbí Allāhu?” Kò sí ẹni tí ó ṣàbòsí tó ẹni tó daṣọ bo ẹ̀rí ọ̀dọ̀ rẹ̀ (tí ó sọ̀kalẹ̀) láti ọ̀dọ̀ Allāhu? Allāhu kò sì níí gbàgbé ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 1