A tún rán (ẹnì kan) sí àwọn ìran Thamūd, arákùnrin wọn Sọ̄lih. Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ìjọ mi, ẹ jọ́sìn fún Allāhu. Ẹ kò ní ọlọ́hun kan tí a gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo lẹ́yìn Rẹ̀. Ẹ̀rí kan (iṣẹ́ ìyanu kan) kúkú ti dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Olúwa yín; èyí ni abo ràkúnmí Allāhu. (Ó jẹ́) àmì kan fún yín. Nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, kí ó máa jẹ kiri lórí ilẹ̀ Allāhu. Ẹ má ṣe fi ọwọ́ aburú kàn án nítorí kí ìyà ẹlẹ́ta-eléro má baà jẹ yín.