Dájúdájú Olúwa yín ni Allāhu, Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, Ó gúnwà sí orí Ìtẹ́-ọlá. Ó ń fi òru bo ọ̀sán lójú, tí òru ń wá ọ̀sán ní kíákíá.[1] Òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ni wọ́n ti rọ̀ pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀. Gbọ́! TiRẹ̀ ni ẹ̀dá àti àṣẹ. Ìbùkún ni fún Allāhu, Olúwa gbogbo ẹ̀dá. 1