Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ẹ̀san Rẹ̀?[1] Lọ́jọ́ tí ẹ̀san Rẹ̀ bá dé, àwọn tó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.² 1