Àwọn tó ń tẹ̀lé Òjíṣẹ́ náà, Ànábì aláìmọ̀ọ́nkọmọ̀ọ́nkà, ẹni tí wọ́n yóò bá àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀ lọ́dọ̀ wọn nínú at-Taorāh àti al-’Injīl, tí ó ń pa wọ́n láṣẹ ohun rere, tí ó ń kọ ohun burúkú fún wọn, tí ó ń ṣe àwọn n̄ǹkan dáadáa ní ẹ̀tọ́ fún wọn, tí ó sì ń ṣe àwọn n̄ǹkan àìdáa ní èèwọ̀ fún wọn, tí ó tún máa gbé ẹrù (àdéhùn tó wúwo) àti àjàgà tó ń bẹ lọ́rùn wọn[1] kúrò fún wọn; àwọn tó bá gbàgbọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n bu iyì fún un, tí wọ́n ràn án lọ́wọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé ìmọ́lẹ̀ náà (ìyẹn, al-Ƙur’ān) tí A sọ̀kalẹ̀ fún un, àwọn wọ̀nyẹn, àwọn ni olùjèrè. 1