Dájúdájú àwọn tó gbàgbọ́ ní òdodo, tí wọ́n gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, tí wọ́n sì fi dúkìá wọn àti ẹ̀mí wọn jagun lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, àti àwọn tó gbà wọ́n sọ́dọ̀ (nínú ìlú), tí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́; àwọn wọ̀nyẹn, apá kan wọn l’ọ̀rẹ́ apá kan (tó lè jogún ara wọn). Àwọn tó gbàgbọ́, tí wọn kò sì gbé ìlú wọn jù sílẹ̀, kò lẹ́tọ̀ọ́ fún yín láti mú wọn lọ́rẹ̀ẹ́ níbì kan kan (tó lè mu yín jogún ara yín), títí wọn yóò fi gbé ìlú wọn jù sílẹ̀.[1] Tí wọ́n bá sì wá ìrànlọ́wọ́ yín (lórí ọ̀tá) nípa ẹ̀sìn, ìrànlọ́wọ́ náà di dandan fún yín àyàfi lórí ìjọ kan tí àdéhùn ń bẹ láààrin ẹ̀yin àti àwọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 1