Masuk
Masuk
Masuk
Pilih Bahasa

Hud 11:98 يقدم قومه يوم القيامة فاوردهم النار وبيس الورد المورود ٩٨

Halaman 209 · Juz 12

یَقْدُمُ
قَوْمَهٗ
یَوْمَ
الْقِیٰمَةِ
فَاَوْرَدَهُمُ
النَّارَ ؕ
وَبِئْسَ
الْوِرْدُ
الْمَوْرُوْدُ
۟
Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú.
reading-goal:continue-reading

Membaca q-and-a.tafsir

Ibn Kathir (Abridged)

The Story of Musa and Fir`awn

In these verses Allah informs of His sending Musa with His signs and clear proofs to Fir'awn, the king of the Coptic people, and his chiefs.

فَاتَّبَعُواْ أَمْرَ فِرْعَوْنَ

(but they followed the command of Fir`awn.) This means that they followed his path, way and methodo

…

The Story of Musa and Fir`awn

In these verses Allah informs of His sending Musa with His signs and clear proofs to Fir'awn, the king of the Coptic peop

…
Melihat tafsirs

Membaca related-content

96. Dájúdájú A fi àwọn àmì Wa àti ẹ̀rí pọ́nńbélé rán (Ànábì) Mūsā níṣẹ́ 97. sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì tẹ̀lé àṣẹ Fir‘aon. Àṣẹ Fir‘aon kò sì jẹ́ ìmọ̀nà. 98. Ó máa ṣíwájú ìjọ rẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ó sì máa kó wọn wọ inú Iná. Wíwọ Iná náà sì burú. 99. A fi ègún tẹ̀lé wọn nílé ayé yìí àti ní Ọjọ́ Àjíǹde. Ẹ̀bùn náà tí wọ́n fún wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé (ègún àti Iná) sì burú. 100. Ìyẹn wà nínú àwọn ìró ìlú tí À ń sọ ìtàn rẹ̀ fún ọ. Ó wà nínú àwọn ìlú náà èyí tí ó sì ń jẹ́ ìlú àti èyí tí wọ́n ti parẹ́. 101. A kò ṣàbòsí sí wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn. Nítorí náà, àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n ń pè lẹ́yìn Allāhu, kò rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ n̄ǹkan kan nígbà tí àṣẹ Olúwa rẹ dé. Wọn kò ṣe àlékún kan fún wọn bí kò ṣe ìparun. 102. Báyẹn ni ìgbámú Olúwa rẹ. Nígbà tí Ó bá gbá àwọn ìlú alábòsí mú, dájúdájú Ó máa gbá a mú pẹ̀lú ìyà ẹlẹ́ta-eléro tó le. 103. Dájúdájú àmì (fèyíkọ́gbọ́n) wà nínú ìyẹn fún ẹnikẹ́ni tó páyà ìyà Ọjọ́ Ìkẹ́yìn. Ìyẹn ni ọjọ́ tí A óò kó àwọn ènìyàn jọ fún. Àti pé ìyẹn ni ọjọ́ tí gbogbo ẹ̀dá yóò fojú rí. 104. A kò sì níí fi falẹ̀ bí kò ṣe títí di àkókò kan tí A ti ṣírò kalẹ̀. 105. Ní ọjọ́ tó bá dé, ẹ̀mí kan kò níí sọ̀rọ̀ àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Olórí burúkú àti olórí ire yó sì wà nínú àwọn ẹ̀dá (ní ọjọ́ náà). 106. Ní ti àwọn tó bá ṣorí burúkú, wọn yóò wà nínú Iná. Wọn yóò máa gbin tòò, wọn yó sì máa ké tòò. 107. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdiwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Aṣèyí-ó-wùú. 108. Ní ti àwọn tí A bá ṣe ní olórí-ire, wọ́n máa wà nínú Ọgbà Ìdẹ̀ra. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀ ní òdíwọ̀n ìgbà tí àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ fi ń bẹ, àfi ohun tí Olúwa rẹ bá fẹ́. (Ọgbà Ìdẹ̀ra jẹ́) ọrẹ àìlópin. 109. Nítorí náà, má ṣe wà nínú iyèméjì nípa ohun tí àwọn wọ̀nyí ń jọ́sìn fún. Wọn kò jọ́sìn fún kiní kan bí kò ṣe bí àwọn bàbá wọn náà ṣe ń jọ́sìn (fún àwọn òrìṣà) ní ìṣáájú. Dájúdájú Àwa yóò san wọ́n ní ẹ̀san ìpín (ìyà) wọn láì níí dín in kù.

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

reading-goal:continue-reading

Catatan dan Refleksi

reflection-not-available

Notes placeholders

Tetap Terhubung dengan Al-Quran ❤️

Pengingat singkat dan bermakna untuk menyegarkan diri, merenung, dan tetap terhubung dengan Al-Quran.

Baca, Dengarkan, Cari, dan Renungkan Al Quran

Quran.com adalah platform tepercaya yang digunakan jutaan orang di seluruh dunia untuk membaca, mencari, mendengarkan, dan merefleksikan Al-Qur'an dalam berbagai bahasa. Platform ini menyediakan terjemahan, tafsir, tilawah, terjemahan kata demi kata, dan berbagai alat untuk pembelajaran yang lebih mendalam, sehingga Al-Qur'an dapat diakses oleh semua orang.

Sebagai sebuah Sadaqah Jariyah, Quran.com berdedikasi untuk membantu orang-orang terhubung secara mendalam dengan Al-Qur'an. Didukung oleh Quran.Foundation , sebuah organisasi nirlaba 501(c)(3), Quran.com terus berkembang sebagai referensi yang sangat bernilai dan gratis untuk semua orang, Alhamdulillah.

Navigasi
Halaman Utama
Radio Qur'an
Qari
Tentang Kami
Pengembang
Pengkinian Produk
Beri Masukan
Bantuan
Menyumbang
Proyek Kami
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Proyek nirlaba yang dimiliki, dikelola, atau disponsori oleh Quran.Foundation
Link populer
Doa-doa dari Al-Quran
Ayat Al-Quran Hari Ini
Ayat Kursi
Surah Yasin
Surah Al Mulk
Surah Ar-Rahman
Surah Al Waqi'ah
Surah Al Kahfi
Surah Al Muzzammil
Peta situsKerahasiaanSyarat dan Ketentuan
© 2026 Quran.com. Hak Cipta Terlindungi
Menyumbang