Войти
Войти
Войти
Выберите язык

Al-Fath 48:23 سنة الله التي قد خلت من قبل ولن تجد لسنة الله تبديلا ٢٣

Страница 513 · Джуз 26

سُنَّةَ
ٱللَّهِ
ٱلَّتِي
قَدۡ
خَلَتۡ
مِن
قَبۡلُۖ
وَلَن
تَجِدَ
لِسُنَّةِ
ٱللَّهِ
تَبۡدِيلٗا
٢٣
Ìṣe Allāhu, èyí tó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú (ni èyí). O ò sì níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu (lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀).
reading-goal:continue-reading

Читать q-and-a.tafsir

Russian Tafseer Al Saddi

Именно так поступал Аллах во времена предыдущих посланников, и никто не в силах изменить Его установления.
Вид tafsirs

Читать related-content

18. Dájúdájú Allāhu ti yọ́nú sí àwọn onígbàgbọ́ òdodo nígbà tí wọ́n ń ṣàdéhùn fún ọ lábẹ́ igi (pé àwọn máa dúró tì ọ́ lójú ogun Hudaebiyyah). Nítorí náà, (Allāhu) mọ ohun tí ó wà nínú ọkàn wọn. Ó sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún wọn. Ó sì san wọ́n ní ẹ̀san ìṣẹ́gun tó súnmọ́ (ìyẹn ogun Hudaebiyyah) 19. àti àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí wọn yóò rí kó. Allāhu ń jẹ́ Alágbára, Ọlọ́gbọ́n. 20. Àti pé Allāhu ṣàdéhùn àwọn ọrọ̀ ogun ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ tí ẹ̀yin yóò rí kó fún yín. Ó sì tètè mú èyí wá fún yín. Ó tún kó àwọn ènìyàn lọ́wọ́ ró fún yín nítorí kí ó lè jẹ́ àmì kan fún àwọn onígbàgbọ́ òdodo àti nítorí kí Ó lè fi ẹsẹ̀ yín rinlẹ̀ sójú ọ̀nà tààrà (’Islām). 21. Àti òmíràn tí ẹ kò lágbára lórí rẹ̀, (àmọ́ tí) Allāhu ti rọkiriká rẹ̀. Allāhu sì ń jẹ́ Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan. 22. Tí ó bá jẹ́ pé àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ gbógun dìde si yín ni, wọn ìbá pẹ̀yìndà (láti ságun fún yín). Lẹ́yìn náà, wọn kò níí rí aláàbò tàbí alárànṣe kan. 23. Ìṣe Allāhu, èyí tó ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú (ni èyí). O ò sì níí rí ìyípadà fún ìṣe Allāhu (lórí àwọn ọ̀tá Rẹ̀). 24. Òun sì ni Ẹni tí Ó kó wọn lọ́wọ́ ró fún yín. Ó sì kó ẹ̀yin náà lọ́wọ́ ró fún wọn nínú ìlú Mọkkah lẹ́yìn ìgbà tí Ó ti fi yín borí wọn. Allāhu sì ń jẹ́ Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́. 25. Àwọn (ọ̀ṣẹbọ) ni àwọn tó ṣàì gbàgbọ́, tí wọ́n ṣẹ yín lórí kúrò ní Mọ́sálásí Haram, tí wọ́n tún de ẹran ọrẹ mọ́lẹ̀ kí ó má lè dé àyè rẹ̀. Tí kì í bá ṣe ti àwọn ọkùnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo àti àwọn obìnrin (tí wọ́n ti di) onígbàgbọ́ òdodo (nínú ìlú Mọkkah), tí ẹ̀yin kò sì mọ̀ wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ pa wọ́n, kí ẹ̀yin má lọ fara kó ẹ̀ṣẹ̀ láti ara wọn nípasẹ̀ àìmọ̀, (Allāhu ìbá tí ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn. Allāhu ko yín lọ́wọ́ ró fún wọn sẹ́) nítorí kí Ó lè fi ẹni tí ó bá fẹ́ sínú ìkẹ́ Rẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé wọ́n wà ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni (onígbàgbọ́ òdodo lọ́tọ̀, aláìgbàgbọ́ lọ́tọ̀), Àwa ìbá jẹ àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ nínú wọn ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro. 26. (Rántí) nígbà tí àwọn tó ṣàì gbàgbọ́ kó ìgbónára sínú ọkàn wọn ní ìgbónára ti ìgbà àìmọ̀kan, Allāhu sì sọ ìfọ̀kànbalẹ̀ kalẹ̀ fún Òjíṣẹ́ Rẹ̀ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo. Ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rù (Rẹ̀) wà pẹ̀lú wọn; Wọ́n ní ẹ̀tọ́ sí i jùlọ, àwọn ni wọ́n sì ni ín. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

reading-goal:continue-reading

Примечания и Размышления

reflection-not-available

Notes placeholders

Оставайтесь на связи с Кораном ❤️

Короткие, но содержательные напоминания, чтобы перезагрузиться, поразмышлять и оставаться на связи с Кораном.

Читайте, слушайте, ищите и размышляйте над Кораном

Quran.com — это надёжная платформа, используемая миллионами людей по всему миру для чтения, поиска, прослушивания и размышления над Кораном на разных языках. Она предоставляет переводы, тафсир, декламацию, пословный перевод и инструменты для более глубокого изучения, делая Коран доступным каждому.

Quran.com, как садака джария, стремится помочь людям глубже проникнуть в Коран. При поддержке Quran.Foundation , некоммерческой организации, имеющей статус 501(c)(3), Quran.com продолжает развиваться как бесплатный и ценный ресурс для всех. Альхамдулиллях.

Навигация
Дом
Коран Радио
Чтецы
О нас
Разработчики
Обновления продуктов
Обратная связь
Помощь
Пожертвовать
Наши проекты
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Некоммерческие проекты, принадлежащие, управляемые или спонсируемые Quran.Foundation
Популярные ссылки
Молитвы из Корана
Аят дня из Корана
Ayatul Kursi
Surah Yaseen
Surah Al Mulk
Surah Ar-Rahman
Surah Al Waqi'ah
Surah Al Kahf
Surah Al Muzzammil
Карта сайтаКонфиденциальностьУсловия и положения
© 2026 Quran.com. Все права защищены
Способствовать