Войти
Войти
Войти
Выберите язык

Al-Fath 48:15 سيقول المخلفون اذا انطلقتم الى مغانم لتاخذوها ذرونا نتبعكم يريدون ان يبدلوا كلام الله قل لن تتبعونا كذالكم قال الله من قبل فسيقولون بل تحسدوننا بل كانوا لا يفقهون الا قليلا ١٥

Страница 512 · Джуз 26

سَيَقُولُ
ٱلۡمُخَلَّفُونَ
إِذَا
ٱنطَلَقۡتُمۡ
إِلَىٰ
مَغَانِمَ
لِتَأۡخُذُوهَا
ذَرُونَا
نَتَّبِعۡكُمۡۖ
يُرِيدُونَ
أَن
يُبَدِّلُواْ
كَلَٰمَ
ٱللَّهِۚ
قُل
لَّن
تَتَّبِعُونَا
كَذَٰلِكُمۡ
قَالَ
ٱللَّهُ
مِن
قَبۡلُۖ
فَسَيَقُولُونَ
بَلۡ
تَحۡسُدُونَنَاۚ
بَلۡ
كَانُواْ
لَا
يَفۡقَهُونَ
إِلَّا
قَلِيلٗا
١٥
Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni. (Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”² Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀.
reading-goal:continue-reading

Читать q-and-a.tafsir

Russian Tafseer Al Saddi

После упоминания о маловерах, которые отказались от священной борьбы, Аллах сообщил о наказании, которое ожидает их в земной жизни. Когда они увидят, как посланник Аллаха, да благословит его Аллах и приветствует, вместе со своими сподвижниками собирается в поход за трофеями, которые достанутся им бе…
После упоминания о маловерах, которые отказались от священной борьбы, Аллах сообщил о наказании, которое ожидает их в земной жизни. Когда они увидят, …
Вид tafsirs

Читать related-content

11. Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun ẹ̀sìn nínú àwọn Lárúbáwá oko yóò máa wí fún ọ pé: “Àwọn dúkìá wa àti àwọn ará ilé wa l’ó kó àìrójú bá wa. Nítorí náà, tọrọ àforíjìn fún wa.” Wọ́n ń fi ahọ́n wọn wí ohun tí kò sí nínú ọkàn wọn. Sọ pé: “Ta ni ó ní ìkápá kiní kan fún yín lọ́dọ̀ Allāhu tí Ó bá gbèrò (láti fi) ìnira kàn yín tàbí tí Ó bá gbèrò àǹfààní kan fún yín? Rárá (kò sí). Allāhu sì ń jẹ́ Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.” 12. Rárá (kì í ṣe iṣẹ́ kan l’ó di yín lọ́wọ́ láti lọ jagun, àmọ́) ẹ ti lérò pé Òjíṣẹ́ àti àwọn onígbàgbọ́ òdodo kò níí padà sí ọ̀dọ̀ ará ilé wọn mọ́ láéláé. Wọ́n ṣe ìyẹn ni ọ̀ṣọ́ sínú ọkàn yín. Ẹ sì ro èrò aburú. Ẹ sì jẹ́ ìjọ ìparun. 13. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, dájúdájú Àwa ti pèsè Iná sílẹ̀ de àwọn aláìgbàgbọ́. 14. Ti Allāhu ni ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Ó ń ṣàforíjìn fún ẹni tí Ó bá fẹ́. Ó sì ń jẹ ẹni tí Ó bá fẹ́ níyà. Allāhu sì ń jẹ́ Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run. 15. Àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun (Hudaebiyyah) ń wí pé: “Nígbà tí ẹ bá ń lọ síbi ọrọ̀-ogun (Kọebar) nítorí kí ẹ lè rí i kó, ẹ fi wá sílẹ̀ kí á lè tẹ̀lé yín lọ.” (Àwọn olùsásẹ́yìn wọ̀nyí) sì ń gbèrò láti yí ọ̀rọ̀ Allāhu padà ni. (Ìwọ Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a -) sọ (fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun Hudaebiyyah) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé wa. Báyẹn ni Allāhu ṣe sọ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àwọn olùsásẹ́yìn náà sì ń wí pé: “Rárá (kò rí bẹ́ẹ̀), ẹ̀ ń ṣe kèéta wa ni.”² Rárá (ẹ̀yin kò ṣe kèéta wọn, àmọ́), wọ́n kì í gbọ́ àgbọ́yé (ọ̀rọ̀) àfi díẹ̀. 16. Sọ fún àwọn olùsásẹ́yìn fún ogun nínú àwọn Lárúbáwá oko pé: “Wọ́n máa pè yín sí àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ní agbára ogun jíjà gan-an. Ẹ máa jà wọ́n lógun tàbí kí wọ́n juwọ́ jusẹ̀ sílẹ̀ (fún ’Islām). Tí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ (yìí), Allāhu yóò fún yín ní ẹ̀san tó dára. Tí ẹ̀yin bá sì pẹ̀yìndà gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe pẹ̀yìndà ṣíwájú, (Allāhu) yó sì fi ìyà ẹlẹ́ta-eléro jẹ yín. 17. Kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún afọ́jú, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún arọ, kò sì sí ẹ̀ṣẹ̀ fún aláìsàn (tí wọn kò bá lọ sójú ogun). Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, (Allāhu) yóò mú un wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra kan, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì pẹ̀yìndà, Ó máa jẹ ẹ́ ní ìyà ẹlẹ́ta-eléro.

- Shaykh Abu Rahimah Mikael Aykyuni

reading-goal:continue-reading

Примечания и Размышления

reflection-not-available

Notes placeholders

Оставайтесь на связи с Кораном ❤️

Короткие, но содержательные напоминания, чтобы перезагрузиться, поразмышлять и оставаться на связи с Кораном.

Читайте, слушайте, ищите и размышляйте над Кораном

Quran.com — это надёжная платформа, используемая миллионами людей по всему миру для чтения, поиска, прослушивания и размышления над Кораном на разных языках. Она предоставляет переводы, тафсир, декламацию, пословный перевод и инструменты для более глубокого изучения, делая Коран доступным каждому.

Quran.com, как садака джария, стремится помочь людям глубже проникнуть в Коран. При поддержке Quran.Foundation , некоммерческой организации, имеющей статус 501(c)(3), Quran.com продолжает развиваться как бесплатный и ценный ресурс для всех. Альхамдулиллях.

Навигация
Дом
Коран Радио
Чтецы
О нас
Разработчики
Обновления продуктов
Обратная связь
Помощь
Пожертвовать
Наши проекты
Quran.com
Quran For Android
Quran iOS
QuranReflect.com
Quran.AI
Sunnah.com
Nuqayah.com
Legacy.Quran.com
Corpus.Quran.com
Некоммерческие проекты, принадлежащие, управляемые или спонсируемые Quran.Foundation
Популярные ссылки
Молитвы из Корана
Аят дня из Корана
Ayatul Kursi
Surah Yaseen
Surah Al Mulk
Surah Ar-Rahman
Surah Al Waqi'ah
Surah Al Kahf
Surah Al Muzzammil
Карта сайтаКонфиденциальностьУсловия и положения
© 2026 Quran.com. Все права защищены
Способствовать