Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀,[1] nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fún yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà. 1